Mo Gbé Owó Mi Sókè Síi Yín (Àdúrà)

Artist: Congress MusicFactory
Produced By: Congress MusicFactory
Album: Ajúbà Re

Ejé kí a gbé owó mímó s‘ókè láti yin olúwa. Bàbá àwa agbé owó o wa sókè síi yín. Ní àpapò, gbogbo wa fìyìn fún un yín. Arákùnrin mi àti Arábìrin úngbé owóo rè sókè ní ègbéè mi. Ní àpapò, à ngbé owóo wa sókè bi àwon eni ìsájú tí wón ti lo sínú ayérayé. Àn únwo bí ìfarajì, ìgbàgbó, ìgbóran àti ìwà mímó wón sé la ònà fún àwa tí àán gbé òpin ayé. Àn únwo àwon tó dúró shin-shin ní nú ìgbàgbó, tí wón di aláìní, tí wón dá lóró, tí wón sì fi èmíi won lélè pèlú èjè won láti lè tan ìmólè sí ònà tí àwa úntò lónî. Mo únse ìrántí ìlànà òtitó tí wón fi lelè ìgbágbó tó ye kòrò, tí yó sì fi ràn wá lówó láti dà bí Krístì nínú ohun gbogbo. Àwon òrò Olórun tí wón fi tokàn, tokàn tè lé ìpinu won láti rìn nínú iwa mímó, igboran si olúwa ati ìgbàgbó tó yè koro fún odún pípé láì se iye méjì. Èyí ni ó jé àwòkóse fún àwa tí àn ngbé ní òpin ayé.

Mo kún fún opé fún ìyìn…fún àí yipàdà yín àti fún òdodo yín àti fún ìpinu láti rán èmí mímó sí nú Okàan wa. Ò hun ni yó sì ma kówa láti rìn nínú ìlànà yín. A kún fún opé. opé nítorípé efún wa ní ìyè àìnípèkun àn úndúpé, okàan wa sí ùnkorin ìyìn síi yín àn úndúpé fún ìmólè yín tó tàn sínú okàan wa bí a ti fìmò pò láti gbée yín ga àti láti máa yìnyìn Bí a ti úngbó ohun tí èmí mímó unso láti enu àwon olùdarí wa, ó únjé kí a kún fún ayà àti láti gbé ojú wa sókè sí oba àìnípèkun A sì ínrí ògo, Olá àti Ewà Olórun Wíwo ojúu yín so mí di eni òtun Wíwo ojúu yín bàbá, wíwo ìfé okàn yín, ni óún yímipadàtí ó sì somí di eni òtun, mo wá dúpé lówóo yín.

Modúpé fún ìpamóò mi, mo sì dúpé fún ìdarí mí. Modúpé fún owóo yín tíó wàlorí ayéè mi. Modúpé pé e fún mí ní ìyè Modúpé fún sùúrù tí efin kó mi. Modúpé pé edaríì mi jáde kúrò nínú ìwà òmùgò sí nú Ogbón. Modúpé pé e mú mi kúrò nínú àìlera, e sìn fún mi ní okun àti ágara. Modúpé pé e múmi kúrò nínú iyè méjì e sì fún mi ní àgbàgbó tó yè koro. Modúpé pé e gbà mí lówó ayé, ikú àti èsè e sì fún mi ní èkúnréré ìyè tó dájú. Modúpé pé e yo mí kúrò nínú aláìlénìyàn e si fi mi si aarin awon eniyan Pataki. Modúpé pé e mú mi kúrò nínú àwon alárìnkà e fún mi ní ìrìn àjò tó dájú. Mo kún fún opé. Modúpé olórun! Modúpé pé e dámi. Modúpé pé e fú mi ní ìyè. Modúpé pé e fi àmì òróró yànmí. Modúpé pé e rán mi sí inú ìyìnrere. Modúpé pé eyàn mí. Modúpé bí e se úntó mi sónà

Modúpé! Modúpé! Modúpé!

Modúpé fún gbogbo ìrìn mi nínú aginjù. Modúpé fún gbogbo ìdánwò. Mo sì dúpé fún gbogbo ìségun tí e fi fúnmi. Modúpé fún gbogbo àwon ibi tíò rorùn tí mo ti rìn nínú ayé yî. Modúpé fún ohun gbogbo, Modúpé, mo láyò, mo sì yìnyín lógo . Títí ayé ni úò’sìmáa gbée yín ga. àmín.