Ònà Nâ (Àdúrà)

Artist: Congress MusicFactory
Produced By: Congress MusicFactory
Album: Ajúbà Re

A kó nínú ìwé mímó wípé ìwo yíó síì gbó ohùn Èmí Olórun tó nso wípé “èyí ni ònà nâ, má a rìn nínú re. E Jékí ohùn yí máa tówa sónà nínú ohun gbogbo tí àá nse. Mo fé kí gbogbo awón ènìyàn gbó ohùn yî. Ohùn Olúwa léyìn re tó ndarí wa, tó sí ùnso wipe, “èyí ni ònà nâ, má a rìn nínú re’

Jékí nma gbó ohùn yí, nínú gbogbo ìrìn àjò ayéè mi. Nígbàtì kò sí ìtosónà fún òpòlòpò ènìyàn

“E jé kí awá gbó ohùn olúwa tó nso nínú ókàan wa wípé èyí ni ònà nâ, má a rìn nínú re’ Asì únberè wípé olórun e jé kí ìtosónà yín yé wa yéké yéké kósì múná dóko nínú ókàn wa. E fún wa ní òye láti mo ìyàtò láarín oun tó jé ti olórun atí èyí ti kó nse ti olórun èyí tó jé odódó yàtó si ohun ìbàjé atí àiàmó; ohun tí ó jé otító àti àìsòtító. Mú wa gbó ohùn yí nínú okàn wa tó únso fún wa wípé èyí ni ònà nâ, má a rìn nínú re’

Fún wa ní ìtónà láti òrun wá àti ìtosónà olórun, tó dájú láti ibi àse, tó gajù lo.Tó ga ju gbogbo ìrúkèrúdò aiyé yî tó ga ju àwon iró re àti ìmò èdá tó ga ju àimó àti ìdibàjé rè. Èyí ni ònà nâ, má a rìn nínú re’ Láti àsìkòyí lo títí dé òpin aiyé nínú gbogbo oun tí èyin yío se pèlú agbára nlá yín. E la ipa-ònà ìmólè tó ntàn lo tàarà síbi ìté ògo yín

E fún wa ní ìgbàgbó láti fi esè wa múlè nínú ònà nâ bí ase ún gbó nínú okàn wa èyí ni ònà nâ, má a rìn nínú re’