Bà Lé Wa

Artist: Congress MusicFactory
Produced By: Congress MusicFactory
Album: Ajúbà Re

[Ese]

Nípa èmí ìre ati d’òtun
Ìrìn àjò yí fún wá l’ókun
Tún mí sí wa léè kan si
Sòkalè sórí wa wá dúró

[Ègbè]

Jékí èmí re, èmí ogbón
Ìmò àti agbára
Tó wá sórí Krístì
Ìmòràn àti òye
Ìbèrù olúwa tó jé ìdùnúù re
Bà lé wa

[Àsopò orin]

Fì fé pípé re hàn
Fi pàtó ìmòóse hàn
Agbára láti se
Ohun tó wà lókàn re
Bí a se únlo ní nú ìfihàn ojó iwájú
Jé kí èso rèe hàn nínúu wa
Olúwa