Erán Wa (Àdúrà)

Artist: Congress MusicFactory
Produced By: Congress MusicFactory
Album: Ajúbà Re

Èyin ni ìsinmiì mi.
Èyin lòpin ìrìn àjò mi
E fún wa ní okun àti agbára yín
Ohun tí a bèrè fún ni àsìkò yí ni kí e Rán wa láti jé isé iyin rere
E rán wa.
Ìgbà ìsimi kó ni awàyí. A fé se isé ìránsé yín tokàn tokàn
A ó sé kára kára,
Ohun tí a nbèrè ni wípé “kí e rán wa sínú Ogbà àjàrà yín.
A ó bèrè fún ìsinmi, ìsinmi yî o wà nígbà tí a bá dé òpin ìrìn àjòo wa

Gbogbo èbè wa ni wípé kí e rán wa láti se isé yín
E rán wa láti se isé ajíhìn rere.

E so wá di òtun nípa Èmí mímó yín. E so gbogbo wa di òkan, nípa Èmí mímó yín.
E dì wá ní àmùrè, kí e sì fún wa ní Agbára fún àwon nkan tí e ní Lókàn yín fún wa láti se, ni ojó iwájú. E jé kí a kún fún ìmólè àti òye. Pèlú ìmò àti agbára

E rán wa lo pèlú ìwà bí Olórun tó kún òsùwòn. ìpinu wa ni láti rìn nínú ìwà mímó àti ìyara-eni sótò
Eya okàn wa sí mímó. Kí a lè gbé ìgbesí ayé tí kò ní àbàwón àti èsè. E rán wa lo pèlú àyà funfun àti okàn mímó. e rán wa lo, Olúwa. E rán wa pèlú agbára nlá yín láti se ohun tó wà nínú Okàn yín Ní gbogbo wa ní àpapò, kí arìn nínú ìwà mímó E fún okàn wa ní àláafíà láti òkè òrun wá

E fúnwa ni èkún-réré ayò. E fún wa ní ìdùnù àti ìtélórùn. E jékí isé nlá yi, mú ìtélórùn wa sínú okàn wa asì–únpòùngbe láti rí Ojú rere yín.Eléyi ni èbè atí àdúrà wa. Àwon nkan wònyí ni ó jewá lókàn. Fún ìdí èyí, agbé okàn wa sókè sí yín

E gbó ohùn àdúrà wa. E gbó èbè àwa ènìyàn yín. E gbàdúrà wa gégé bí ìlànà ti Jésù Kriístì olúwa wa. Adúpé pé eti gbó àdúrà wa. A dúpé, Jésù, Omo Olórun adúpé.